THE OBANIKORO FAMILY PANEGYRICS (ORIKI)

Omo Obanikoro Abebe Joye

Omo Oluwo Nla

Omo Asape Ola ti nfi Eran Nla bo Ifa

Omo Orogun Ejiga

Omo Apa Feye je

Omo Aromadahun

Omo Aga Bi Erin

Omo Iroko Lado, Osanyin Lawe

Omo Apekan Ma Ha Obinrin, Ti Nsin

Ohun Oro Le Egungun Lori

Omo Apa Won N i ‘jo Iku Ko Wun Won Ku

Ti Ngbani mo Tintin  Pa

Nmoje, nmoro ji,

Omo Egba Oloja, Ota Amoye

Omo Olota Ado, Omo Aro Dede wo mi

Omo Awi ma ti mo se

Omo Awi Be Se be,

Omo Adagba Soogun Soogun

Omo Ojumo kan Ogun kan

Bofe, Bofe , Tulasi Ni

Omo Alaran, Oyiyi

Omo Ayigun Lagbele

Omo Awo Ifetoro

Ogidi Olu, Oniganga Aji Pon

Obomi Osuru we’ da

Eni Ajayi Gba ! Gba!! Gba!!!, Ti Ko Le Gba Tan

Gunnugun ni yio Gba Oluwa Re

Ajayi Gba mi o, Arile Wa

Omo Obanikoro Gba mi.

Hits: 372